Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 289: A Ó Ṣiṣẹ́! A Ó Ṣiṣẹ́!
To the Work! To the Work!
A ó ṣiṣẹ́! a ó ṣiṣẹ́!
Ọm' Ọlọ́run ni wa!
Jẹ́ k' a tẹ̀ lé ipa tí Olúwa wa tọ
K' a f' ìmọ̀ràn Rẹ sọ agbára wa d' ọ̀tún,
K' a fi gbogbo
Kún wa ṣiṣẹ́ t' a ní ṣe.
Forí tìí, forí tìí, Forít ìí, forí tìí,
Máa rètí, máa ṣọ́nà,
Títí Olúwa yóò fi dé.
A ó ṣiṣẹ́! a ó ṣiṣẹ́! bo àwọn t' ẹ̀bí ń pa,
Kọ àwọn aláàrẹ̀ lọ s' orísun ìyè;
Nínú àgbélébùú l' àwa ó máa s' ògó,
Nígbà tí a ń kédé pé Ọ̀fẹ́ n' ìgbàlà.
Forí tìí, forí tìí, Forít ìí, forí tìí,
Máa rètí, máa ṣọ́nà,
Títí Olúwa yóò fi dé.
A ó ṣiṣẹ́! a ó ṣiṣẹ́! gbogbo wa ni yóò ṣe é,
Ìjọba òkùnkùn àti irọ́ yóò fọ́;
A ó sì gbé orúkọ Jèhófà lékè,
N' nú orin ìyìn wa pé, Ọ̀fẹ́ n' ìgbàlà.
Forí tìí, forí tìí, Forít ìí, forí tìí,
Máa rètí, máa ṣọ́nà,
Títí Olúwa yóò fi dé.
A ó ṣiṣẹ́! a ó ṣiṣẹ́! l' agbára Olúwa.
Agbádá àt' adé yóò sì jẹ́ ère wa;
Nígbà tí a bá àwọn olóòótọ́ gbé,
Gbogbo wa yóò jọ hó pé Ọ̀fẹ́ n' ìgbàlà.
Forí tìí, forí tìí, Forít ìí, forí tìí,
Máa rètí, máa ṣọ́nà,
Títí Olúwa yóò fi dé.