Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 288: Yọ Àwọn Tí Ń Ṣègbé

Rescue the Perishing

Yọ àwọn tí ń ṣègbé, s' àájò ẹni ń kú
F' àánú ja wọ́n kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀
Kẹ f' àwọn tí ń ṣìnà, gb' ẹni ṣubú rò
Sọ fún wọn pé, Jésù lè gbà wọ́n là

Yọ àwọn tí ń ṣègbé, s' àájò ẹni ń kú
Aláànú ni Jésù; yóò sì gbàlà.

Bí wọ́n ó tilẹ̀ gàn-an síbẹ̀ Ó ń dúró
Láti gb' ọmọ t' ó ronú píwàdà;
Ṣàá f' ìtara rò wọ́n, sì rò wọ́n jẹ̀jẹ̀,
Òun ó dàríjì, bí wọ́n jẹ́, gbàgbọ́.

Yọ àwọn tí ń ṣègbé, s' àájò ẹni ń kú
Aláànú ni Jésù; yóò sì gbàlà.

Yọ àwọn tí ń ṣègbé,
Iṣẹ́ tire ni;
Olúwa, yóò fi agbára fún ọ;
Fi sùúrù rò wọ́n, padà s' ọ̀nà tòórò,
Sọ f' aṣako p' Olùgbàlà ti kú.

Yọ àwọn tí ń ṣègbé, s' àájò ẹni ń kú
Aláànú ni Jésù; yóò sì gbàlà.