Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 287: Ṣiṣẹ́ 'Tòrí Órù Ń Bọ̀
Work For The Night Is Coming
Ṣiṣẹ́ 'tòrí órù ń bọ̀!
Ṣiṣẹ́ ní òwúrọ̀
Ṣiṣẹ́ nígbà ìrí ń ṣe
Ṣiṣẹ́ n' nú tànná;
Ṣiṣẹ́ kí ọ̀sán tó pọn
Ṣiṣẹ́ nígb' oòrùn ń rán;
Ṣiṣẹ́ 'tòrí órù ń bọ̀!
'Gbà 'ṣe ó parí.
Ṣiṣẹ́ 'tòrí órù ń bọ̀!
Ṣiṣẹ́ l' ọ̀sán-an gangan,
F' àkókò rere fún 'ṣe,
Ìsimi dájú,
F' olúkúlùkù ìgbà,
Ní nnkan láti pa mọ́;
Ṣiṣẹ́ 'tòrí órù ń bọ̀,
'Gbà 'ṣe ó parí.
Ṣiṣẹ́ 'tòrí órù ń bọ̀!
Oòrùn fẹ́rẹ̀ wọ̀ nà,
Ṣiṣẹ́ 'gbàt' ìmọ́lẹ̀ wà,
Ọjọ́ bù lọ tán,
Ṣiṣẹ́ títí dé òpin,
Ṣiṣẹ́ títí d' alẹ́,
Ṣiṣẹ́ gbàt' ilẹ̀ bá ń sù,
'Gbà 'ṣe ó parí.