Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 286: Jésù Bá Ìjọ Rẹ Gbé
Jesus With Thy Church Abide
Jésù, bá ìjọ Rẹ gbé
S' Àmọ̀nà àt' Odì rẹ
B' ó ti ń là 'dánwò kọjá;
A ń bẹ Ọ, gbọ́ ti wa.
K' ohùn rẹ̀ máa ja gòòrò,
Ní 'kìlọ̀ 'dájọ́ tí ń bọ̀;
Ní sísọ ìfẹ́ Jésù;
A ń bẹ Ọ, gbọ́ ti wa.
Kọ́ ọ tọ́ àwọn afọ́jú
Wá àwọn t' ó nù kiri,
M' ọkàn t' ó gbọ̀gbẹ̀ dúró;
A ń bẹ Ọ, gbọ́ ti wa.
K' ìjọ yìí jẹ́ aṣẹ́gun;
J' ó borí ogun ẹ̀ṣẹ̀
Kó gbogbo ayé wọlé;
A ń bẹ Ọ, gbọ́ ti wa.