Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 285: 'Pìlẹ̀ Ìjọ Ọlọ́run
The Church's One Foundation
'Pìlẹ̀ ìjọ Ọlọ́run
Ni Jésù Olúwa;
Ó jẹ́ ẹ̀dá Rẹ títun
Pẹ̀l' omi àt' Ọ̀rọ̀,
Ó wá wa láti ọ̀run
Láti fi ṣ' ayà Rẹ;
Ó sì fi ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà á,
Ó kú kí Òun lè yè
A sà wọn níbi gbogbo,
Síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ọkàn
Olúwa kan, 'gbàgbọ́ kan
L' òfin ìgbàlà rẹ̀
Oókọ kan ni wọ́n ń yìn
Ọkàn ni ìrètí wọn,
Ọkàn ni ìrètí wọn
Pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́.
Pẹ̀lú ẹ̀gàn ìyànu
Là rí i b' ó ti ń jìyà
Bí ọ̀tá tilẹ̀ fẹ́ wó
Ódi 'bi sìnmi Rẹ
Ó ń fi ìtara bèèrè
Báwo ni yóò pẹ́ tó?
Láìpẹ́ alẹ́ ẹkún kan
Yóò di oòrọ̀ ayọ̀.
Nínú láálàá oùn 'pọ́njú
L' àárín ogun ayé
Ó ń rètí ọjọ́ 'kẹ́yìn
T' àlàáfíà láéláé,
Títí ojú ìrètí Rẹ
Yóò r' ìràn t' ó l' ògó
Tí ìjọ ńlá t' ó ṣẹ́gun
Yóò sì ní ìsimi.