Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 284: 'Búgbé Rẹ Ti L' Ẹwà Tó
Pleasant Are Thy Courts Above
'Búgbé Rẹ ti l' ẹwà tó!
N' ilé 'mọ́lẹ̀ àt' ìfẹ́
'Búgbé Rẹ ti l' ẹwà tó!
L' ayé ẹ̀ṣẹ̀ àt' òsì;
Ọkàn mi ń fà nítòótọ́,
Sí 'dápọ̀ ènìyàn Rẹ,
Fún ìmọ́lẹ̀ ojú Rẹ,
Fún Okùn Rẹ Ọlọ́run.
Àwọn ẹyẹ, kún f' ayọ̀,
Wọ́n ń fò yí ìtẹ́ Rẹ ká;
Ayọ̀ ọkàn t' ó simi,
L' àyà Bàbá wa Ọ̀run;
Gẹ́gẹ́ b' àdàbà Nóà,
Tí kò r' ibi simi lé,
Wọ́n padà sọ̀dọ̀ Bàbá
Wọ sì ń yọ títí ayé.
Ọkàn t' ó kún fún ìyìn,
Nínú ayé òsì yìí;
Omi ń sun ní àginjù,
Wọ́n ń jẹ manna lát' Ọ̀run,
Wọ́n ń lọ lát' ipa dé 'pa,
Títí wọ́n yóò r' ìtẹ́ Rẹ,
Kí wọ wọlẹ̀l' ẹsẹ̀ Rẹ,
Tó O mú wọn là ewu ja.
Bàbá jẹ́ kí n jèrè 'bẹ̀ẹ̀
Tọ́ mi l' ayé ẹ̀ṣẹ̀ yìí;
F' oore-ọ̀fẹ́ pa mi mọ́,
Fún mi l' àyè l' ọ̀dọ̀ Rẹ
Ìwọ l' Ọ̀run àt' Àsà;
Tọ́ ọkàn ìṣìnà mi;
Ìwọ l' orísun oore,
Rọ̀ ojò Rẹ s' orí mi.