Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 283: N' Nú Gbogb' Ayídáyíd' Ayé
Through All The Changing Scenes Of Life
N' nú gbogb' ayídáyíd' ayé,
N' nú 'yọ̀nú àt' ayọ̀,
Síbẹ̀ ìyìn Ọlọ́run mi
Ni yóò gb' ẹnu mi kan.
N ó s' ògó n' nú ìgbàlà Rẹ,
Tít' àwọn t' ojú ń pọn
Yóò f' àpẹẹrẹ mi ṣe 'tùnú
T' ẹ̀dùn wọn yóò fò lọ.
Àwọn ogun ọ̀run sì yí
'Búgbé olóòótọ́ ká;
Ó j' àábò fún gbogbo àwọn
T' ó gbékèl' oókọ Rẹ.
Ìwọ ṣàá dán ìfẹ́ Rẹ wò,
Ìwọ yóò sì rí I pé
Ọ̀pọ̀ 'búkún l' ó wà f' àwọn
Tí ń gbé 'nú òótọ́ Rẹ.
Bẹ̀rù Rẹ, ẹ kì yóò sì ní
Ìbẹ̀rù míràn mọ́;
Fi iṣẹ́ Rẹ ṣe ayọ̀ rẹ;
'Tọ́jú rẹ d' iṣẹ́ Rẹ.