Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 282: Ìgbà Náà Yóò Ti Dùn Tó

Sweet the Time

Ìgbà náà yóò ti dùn tó,
T' àwọn mímọ́ yóò padé;
Tí Jésù yóò j' orin wọn,
Tí wọ́n yóò kọ orin Rẹ.

Jẹ́ k' a kọ orin ìfẹ́,
T' ó mú Bàbá wa ọ̀run
F' Ọmọ Rẹ 'kanṣoṣo fún wa,
'Gbà t' Ó r' ayé n' ìbàjẹ́.

Kọrin ìfẹ́ Ọmọ náà,
B' Ó ti f' ìtẹ́ ọ̀run 'lẹ̀;
Ó gb' àwọ̀ àt' ipò wa,
Ó kú láti gbà wá là

Jẹ́ k' a kọrin ìf' Ẹ̀mí,
Ẹni t' ó ń rò ọkàn wa,
T' ó ń fi ẹ̀ṣẹ̀ wa hàn wa,
T' ó mú Jésù sún mọ́ wa.

Ìgbà náà yóò ti dùn tó,
T' àwọn mímọ́ yóò padé;
Jésù yóò máa j' orin wọn,
Wọ́n yóò máa kọ orin Rẹ.