Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 280: 'Búkún Ni Fún Ohun T' Ó Dé Wa Pọ̀
Blest Be the Tie that Binds
'Búkún ni fún ohun
T' ó dé wa pọ̀ n' nú 'fẹ́!
Ìdápọ̀ àwọn olùfẹ́
Dàbí ìjọ t' ọ̀run.
Níwájú 'tẹ́ Bàbá
Ni àwa ń gbàdúrà
Ọkàn n' ìrètí àt' ẹ̀rù,
Àti ní ìtùnú.
Àwa ń b' ara wa pín
Nínú wàhálà wa;
Àwa sì ń b' ara wa sọkún
Nínú 'bànújẹ́ wa.
Nígbà ta a bá pínyà,
Inú wa a bàjẹ́;
Síbẹ̀ ọkàn wa yóò j' ọkàn
Ní ìrètí ìpadé.