Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 28: Mo Jí L' Oòrọ̀ Yìí Pẹ̀l' Ẹ̀mí

I Wake This Morn

Mo jí l' oòrọ̀ yìí pẹ̀l' ẹ̀mí
Títun ní inú mi,
Ìgbà t' ó ń bọ̀ sì kún f' ọ̀pọ̀
Ìlérí t' ó l' ọ̀gọ́.

Ọ̀rọ̀ títun wà láti sọ
Àt' èèyàn láti fẹ́;
Bóyá mo lè ṣe oore kan
Lónì n' tórí ìfẹ́.

Ìlérí wà láti mú ṣe,
'Ṣe t' ó yẹ láti ṣe;
K' á lè f' ayọ̀ parí 'ṣe náà
Tí a bẹ̀rẹ̀ l' àná.

'Rúgbìn títun wà lọ́wọ́ mi
Láti fún n' gbà gbogbo,
Níp' èyí tí èso yóò wá
Fún mi àt' elòmíì

L' òwúrọ̀ ọjọ́ títun yìí
Mo f' ara mi fún Ọ
Kí n lè gbé bí Ìwọ ti ń fẹ́,
Kí n sì ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.