Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 279: Jésù Wá Nínú Oore Rẹ
In Loving Kindness Jesus Comes
Jésù wá nínú oore Rẹ
Láti rà ọkàn mi padà,
Kúrò n' nú ẹ̀ṣẹ̀ oùn tìjú,
N' nú àánú Ó yọ mi.
Ó yọ mi kúrò n' nú ẹ̀ṣẹ̀,
Ọwọ́ jẹ̀jẹ̀ l' Ó fi fà mi
Láti òòkùn sí ìmọ́lẹ̀,
Ògo ni fún orúkọ Rẹ.
Ó ti ń pè mi pé kí n tó gbọ́,
K' ọkàn ẹ̀ṣẹ̀ mi tó sójí;
'Gbàtí mo sì gb' ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́,
Ní dàríjì Ó yọ mi.
Ó yọ mi kúrò n' nú ẹ̀ṣẹ̀,
Ọwọ́ jẹ̀jẹ̀ l' Ó fi fà mi
Láti òòkùn sí ìmọ́lẹ̀,
Ògo ni fún orúkọ Rẹ.
A f' adé ẹ̀gún dé E lórí,
A sì kan ọwọ́ Rẹ n' ìsọ,
'Gbà ta a tòr' ẹ̀ṣẹ̀ kọ mi 'lẹ̀
N' nú ìfẹ́ Ó yọ mi.
Ó yọ mi kúrò n' nú ẹ̀ṣẹ̀,
Ọwọ́ jẹ̀jẹ̀ l' Ó fi fà mi
Láti òòkùn sí ìmọ́lẹ̀,
Ògo ni fún orúkọ Rẹ.
Nísiyìí mo ń gbé 'bi gíga,
Mo mọ̀ l' ọkàn mi p' ó dára,
Ṣùgbọ́n ń kò lè sọ ìdí rẹ̀,
Tí Ó fi yọ mi bẹ́ẹ̀.
Ó yọ mi kúrò n' nú ẹ̀ṣẹ̀,
Ọwọ́ jẹ̀jẹ̀ l' Ó fi fà mi
Láti òòkùn sí ìmọ́lẹ̀,
Ògo ni fún orúkọ Rẹ.