Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 278: Ìsimi Wa L' Ọ̀run
Ìsimi Wa L' Ọ̀run
Ìsimi wa l' ọ̀run kò sí l' ayé yìí,
Èmi ó ṣe kún,
gbà tí 'yọ̀nú bá dé?
Simi, ọkàn mi,
Èyí t' ó wù kó dé,
Ó dín àjò mi kù,
Ó mú k' ilé yà.
Kò tó fún mi kí n máa simi
níhìn-in yìí;
Kí n sì máa kọ́ 'lé mi nínú ayé yìí;
Oúngbé ilú t' a a kọ́
f' ọwọ́ kò ń gbé mi,
Mo ń rètí ayé t' ẹ̀ṣẹ̀ kò lè bà jẹ́.
Ẹ̀gún ọ̀ṣùṣù lè máa hù yí mi ká,
Ṣùgbọ́n èmi kò ní gbéra lé ayé;
Èmi kò wá ìsimi kan ní ayé,
Èmi ó fi simi l' àyà Jésù mi.
'Yọ̀nú lè dààmú, ṣùgbọ́n kò
lè pa mi,
Ojú 'fẹ́ Jésù lè sọ 'yọ̀nú d' ẹrín,
Ẹrín Rẹ yóò sọ ẹkún wa d' ayọ̀.
Bí 'gbà t' èfúùfù fé ojò sísù lọ.