Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 277: N Ó Kọrin Olùgbàlà Mi
I Will Sing Of My Redeemer
N ó kọrin Olùgbàlà mi,
Àt' ìfẹ́ 'yànu Rẹ;
Ó jì yà ní orí igi,
K' Ó lè sọ mi d' om'nírà.
K' orin k' orin s' Olùgbàlà mi,
Ó fi ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà mi,
L' ór' igi l' Ó dàríjì mi
Ó san gbogbo gbèsè mi.
N ó sọ 'tàn, àní 'tàn 'yànu,
Bí ó ṣe wá s' ayé
Nínú ìfẹ́ àt' àánú Rẹ
Ó rà mi padà l' ọ̀fẹ́ẹ́.
K' orin k' orin s' Olùgbàlà mi,
Ó fi ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà mi,
L' ór' igi l' Ó dàríjì mi
Ó san gbogbo gbèsè mi.
N ó kọrin Olùgbàlà mi,
Àti ìfẹ́ t' Ó fi fẹ́ mi;
Ó jí mi láti ikú sí ìyè,
Ọ̀dọ̀ Jésù l' ó yẹ mi.
K' orin k' orin s' Olùgbàlà mi,
Ó fi ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà mi,
L' ór' igi l' Ó dàríjì mi
Ó san gbogbo gbèsè mi.