Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 275: A Ti Gb' Ọ̀rọ̀ Ayọ̀ Kan

We Have Heard A Joyful Song

A ti gb' ọ̀rọ̀ ayọ̀ kan,
Pé Jésù ń gbà ní là
Tàn 'hìnrere náà kalẹ̀,
Pé Jésù ń gbà ní là;
Kédé ìhìn ayọ̀ náà,
Lórí 'lẹ̀ àt' èkúsù
Àṣẹ Olúwa wa ni
Jésù yóò gbà wá là.

Kọrin rẹ̀ lórí òkun,
Pé Jésù ń gbà ní là
Sọ f' ẹlẹ́ṣẹ̀ n' bi gbogbo,
Pé Jésù ń gbà ní là
Kọrin ẹ̀yìn èkúsù,
Bú s' ayọ̀ ẹ̀yìn ìgbì
Ayé yóò gbà ìsimi,
Jésù yóò gbà wá là.

Kọrin nígbà ìdánwò,
Pé Jésù yóò gbà là,
Nípa 'kú àt' ìyè Rẹ
Jésù yóò gbà wá là
Kọrin nígbà ìpọ́njú,
Tí ọkàn sì ń fẹ́ àánú
Kọrin 'ṣẹ́gun lór' ikú,
Jésù yóò gbà wá là.

Kọrin ẹ̀yìn afẹ́fẹ́,
Pé Jésù yóò gbà là,
Gbogbo aráyé ẹ yọ,
Jésù yóò gbà wá là
Jẹ́ k' igbó àti ijù,
Y' ayọ̀ ìgbàlà ọ̀fẹ́,
Èyí l' orin 'ṣẹ́gun wa,
Jésù ti gbà wá là.