Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 274: Gbọ́ Ọ̀rọ̀ T' Olùgbàlà
Hark My Soul! It Is The Lord
Gbọ́ ọ̀rọ̀ t' Olùgbàlà
Ń bá ìwọ ọkàn mi sọ;
Ó ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé,
Ẹlẹ́ṣẹ̀, o fẹ́ràn mi?
Ìfẹ́ Mi kì í yí padà,
Ó ga ju òkè ńlá lọ;
Ó jìn ju gbogbo òkun,
Ó lágbára ju ikú.
Láìpẹ́ 'wọ ó f' ògo Mi,
Gbà ṣe àánú bá parí,
Ìbéèrè Mi yóò sì jẹ́!
Ẹlẹ́ṣẹ̀, o fẹ́ràn Mi?
Èyí ni àìlera mi
Ìfẹ́ mi kò gbóná tó;
Bẹ́ẹ̀ mo ń fẹ́, mo sì yìn Ọ:
N' p' oore-ọ̀fẹ́, kí n fẹ́ Ọ sí i.