Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 273: Ìsun Kan Wà T' Ó Kún F' Ẹ̀jẹ̀

There Is A Fountain

Ìsun kan wà t' ó kún f' ẹ̀jẹ̀,
Ó ń sun n' ìhà Jésù
Ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ọkùn nínú rẹ̀
Ó bọ́ nínú ẹ̀bí,
Ó bọ́ nínú ẹ̀bí
Ẹlẹ́ṣẹ̀ mọ́ọkùn nínú rẹ̀
Ó bọ́ nínú ẹ̀bí.

Olè orí àgbélébùú
Yọ láti rí 'sun náà,
Níbẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ bí èmi,
Yóò wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù,
Yóò wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù,
Yóò wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù,
Níbẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ bí èmi,
Yóò wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù.

Jésù mi ẹ̀jẹ̀ Rẹ ọ̀wọ́n,
K' yóò s' agbára rẹ̀ nù;
Títí àwọn t' a a ràpadà,
Yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,
Yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,
Yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀,
Títí àwọn t' a a ràpadà,
Yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Gbà mo f' ìgbàgbọ́ r' ìsun náà.
T' ọgbẹ́ Rẹ ń tú jade;
Ìràpadà d' orin fún mi
Tí n ó máa kọ títí
Tí n ó máa kọ títí
Tí n ó máa kọ títí
Ìràpadà d' orin fún mi
Tí n ó máa kọ títí

Jésù mo gbàgbọ́ pé o pèsè,
Bí mo tilẹ̀ ṣ' àìyẹ,
Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ t' a a f' ẹ̀jẹ̀ rà,
Àti dùúrù wúrà
Àti dùúrù wúrà
Àti dùúrù wúrà
Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ t' a a f' ẹ̀jẹ̀ rà,
Àti dùúrù wúrà

Nínú orin t' ó dùn jù lọ,
L' èmi ó kọrin Rẹ,
'Gbàt' akọlọlọ ahọ́n yìí
Bá dìde n' ìbòjì,
Bá dìde n' ìbòjì,
Bá dìde n' ìbòjì,
'Gbàt' akọlọlọ ahọ́n yìí
Bá dìde n' ìbòjì