Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 272: A Ti Ṣe Ìràpadà Ńlá Mi

Redeemed How I Love To Proclaim It

A ti ṣe ìràpadà ńlá mi
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn
Àti nípa oore-ọ̀fẹ́ ńlá Rẹ
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.

Ìràpadà,
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
A ti ṣe ìràpadà ńlá mi
Ìràpadà
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.

Nígb' ọ̀sán àti nígbà órù
Olùgbàlà mi l' èrò mi,
Èmi kò lè dakẹ́ orin Rẹ
Orin ìyìn ìfẹ́ ńlá Rẹ.

Ìràpadà,
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
A ti ṣe ìràpadà ńlá mi
Ìràpadà
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.

Mo mọ̀ pé n ó rí i nínú ògo,
Ọba, tí mo fẹ́ òfin Rẹ,
T' ó ń ṣọ́ mi ní ọ̀nà mi gbogbo,
Èmi ó kọrin Rẹ l' órù.

Ìràpadà,
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
A ti ṣe ìràpadà ńlá mi
Ìràpadà
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.