Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 271: A Ti Ṣe Ìràpadà Ńlá Mi
Redeemed How I Love To Proclaim it
A ti ṣe ìràpadà ńlá mi,
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn
Àti nípa oore-ọ̀fẹ́ ńlá Rẹ
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.
Ìràpadà
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
Ìràpadà,
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.
'Tòrí náà inú mi dùn jọjọ
Ẹnu kò lè sọ ayọ̀ mi;
Nítorí Òun yóò wà pẹ̀lú mi
Ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.
Ìràpadà
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
Ìràpadà,
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.
Mo mọ̀ pé adé kan wà fún mi,
Ní ayé rere tí ó ń bọ̀:
Ibi ayọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run
Láìpẹ́ èmi ó wà níbẹ̀.
Ìràpadà
Nípa ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn,
Ìràpadà,
N ó j' ọmọ Rẹ títí ayé.