Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 270: Wá, Ìwọ Ìsun Ìbùkún
Come Thou Fount Of Every Blessing
Wá, Ìwọ ìsun ìbùkún
Mú mi kọrin oore Rẹ.
Odò àánú tí ń san títí
Bèèrè orin 'yìn kíkan
Kọ́ mi láti máa júbà Rẹ,
Kí n sì rọ́yìn oore Rẹ,
N' gbà 'rètí ògo àìlópin
Kún ọkàn mi pẹ̀l' ayọ̀.
Níhìn-in l' a ràn mí lọ́wọ́ dé,
Mo gbé Ẹbẹnísà 'rọ̀;
Mo ń rètí nípa 'nú 'rẹ Rẹ,
Kí n dé 'lé l' àlàáfíà
L' àlejò ni Jésù wá mi
'Gbà mo ṣako lọ l' àgbo
Láti yọ mi nínú ẹgbẹ́,
Ó f' ẹ̀jẹ̀ Rẹ s' ẹ̀tùtù.
Nít' oore-ọ̀fẹ́ lójoojúmọ́,
Ni 'gbèsè mi sì ń pọ̀ síi;
K' oore-ọ̀fẹ́ yìí ja ẹ̀wọ̀n
Tí ń ṣe 'dènà ọkàn mi.
Kí n ṣako sáà l' ọkàn mi ń fẹ́,
Kí n kọ Jésù tí mo fẹ́;
Olùgbàlà, gbà ayà mi,
Mú u yẹ f' àgbàlá ọ̀run.