Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 27: Olúwa Mi, Mo Ń Jáde Lọ
Forth in Thy Name O Lord I Go
Olúwa mi, mo ń jáde lọ,
Láti ṣe iṣẹ́ oòjọ́ mi,
Ìwọ nìkan l' èmi ó mọ̀,
L' ọ̀rọ̀ l' èrò àti n' iṣẹ́.
Iṣẹ́ t' Ó yàn mí l' àánú Rẹ̀,
Jẹ́ kí n lè ṣe é t' ayọ̀ t' ayọ̀,
Kí n rí ojú Rẹ̀ ní iṣẹ́ mi,
K' èmi lè fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn.
Ìwọ t' ojú Rẹ̀ r' ọkàn mi,
Máa wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi láé
Kí n máa ṣiṣẹ́ lọ l' àṣẹ Rẹ̀
Kí n fi 'ṣe mi gbogbo sìn Ọ.
Jẹ́ kí n r' ẹrù Rẹ̀ tó fúyẹ́
Kí n máa ṣọ́ra nígbà gbogbo,
Kí n máa f' ojú sí n kan t' ọ̀run
Kí n sì múra d' ọjọ́ ọ̀gọ́.