Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 269: Ògo Fún Ọlọ́run Nítòr' Iṣẹ́ Rẹ

To God be the Glory

Ògo fún Ọlọ́run nítòr' iṣẹ́ Rẹ;
Ó f' Ọmọ Rẹ f' ayé nítorí 'fẹ́ Rẹ,
Ọmọ tó f' ẹ̀jẹ̀ Rẹ s' ẹ̀tùtù f' ẹ̀ṣẹ̀,
Ó sì lékùn ìyè kí a lè wọ 'lé.

Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ k' ayé gbọ́hùn Rẹ;
Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ kí gbogb' èèyàn yọ;
Ẹ wá s' ọ̀dọ̀ Bàbá ní pàṣẹ Jésù,
K' ẹ sì fi Ògo fún Un nítòr' iṣẹ́ Rẹ.

Ìràpadà pípé t' a a fi ẹ̀jẹ̀ rà,
Ìlérí Ọlọ́run ń bẹ f' ẹn' tó gbà gbọ́
Ẹlẹ́ṣẹ̀ búburú t' ó bá ní 'gbàgbọ́
Jésù ṣe tán láti dàr' ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì.

Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ k' ayé gbọ́hùn Rẹ;
Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ kí gbogb' èèyàn yọ;
Ẹ wá s' ọ̀dọ̀ Bàbá ní pàṣẹ Jésù,
K' ẹ sì fi Ògo fún Un nítòr' iṣẹ́ Rẹ.

Ó ti kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ ìyebíye
Inú dídùn wa yóò pọ̀ nínú Jésù;
Ṣùgbọ́n ìyànu wa yóò sì pọ̀ jọjọ
Nígbà tí a bá rí ojú Olúwa.

Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ k' ayé gbọ́hùn Rẹ;
Yìn Jésù, Yìn Jésù,
Jẹ́ kí gbogb' èèyàn yọ;
Ẹ wá s' ọ̀dọ̀ Bàbá ní pàṣẹ Jésù,
K' ẹ sì fi Ògo fún Un nítòr' iṣẹ́ Rẹ.