Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 267: Mo R' Ìgbì 'Múláradà
O Now I See The Cleansing Wave
Mo r' ìgbì 'múláradà
Ìsun t' ó jìn, t' ó fẹ́
Jésù Kríst Olùgbàlà mi
Tọ́ka s' ọgbẹ́ 'hà Rẹ.
Ìsun ìyè mo rí i mo rí i
Mo rí 'nú rẹ̀ ara mi dà?
Yìn Olúwa Ó wò mí san
Ó wò mí san, Ó wò mí san.
Mo rí ẹ̀dá títun ń dìde,
Mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀
Ó sọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ dí 'gbàgbé
Ó rí sí 'nú 'sun náà.
Ìsun ìyè mo rí i mo rí i
Mo rí 'nú rẹ̀ ara mi dà?
Yìn Olúwa Ó wò mí san
Ó wò mí san, Ó wò mí san.
Mo ń rìn 'nú ìmọ́lẹ̀ ọ̀run,
N' bi t' ó ga ju ẹ̀ṣẹ̀;
Pẹ̀l' ọkàn àt' aṣọ mímọ́
Níbi Jésù Jọba.
Ìsun ìyè mo rí i mo rí i
Mo rí 'nú rẹ̀ ara mi dà?
Yìn Olúwa Ó wò mí san
Ó wò mí san, Ó wò mí san.
Oore-ọ̀fẹ́! Ọ̀run sọ kalẹ̀,
Láti wò ẹ̀ṣẹ̀ san;
Jésù nìkan ṣoṣo l' ó mọ̀
Jésù t' a a kàn mọ́ 'gi.
Ìsun ìyè mo rí i mo rí i
Mo rí 'nú rẹ̀ ara mi dà?
Yìn Olúwa Ó wò mí san
Ó wò mí san, Ó wò mí san.