Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 266: Ó Ti Tọ Jésù Lọ Fún Ìwẹ̀nùmọ́?

Have You Been To Jesus For The Cleansing Pow'r

Ó ti tọ Jésù lọ fún ìwẹ̀númọ́?
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn
Ìwọ ha gbékèlé oore-ọ̀fẹ́ Rẹ?
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od' àgùtàn?

A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀
Nínú ẹ̀jẹ̀ tí ń wẹ̀ ọkàn mọ́?
Aṣọ rẹ ha funfun? ó sì mọ́ láúláú
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?

Ó ń bá Olùgbàlà rìn lójoojúmọ́?
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?
Ó ha gbékèlé Ẹni t' a a kàn Mọ́ 'gi
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?

A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀
Nínú ẹ̀jẹ̀ tí ń wẹ̀ ọkàn mọ́?
Aṣọ rẹ ha funfun? ó sì mọ́ láúláú
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?

Aṣọ rẹ ha mọ̀ láti padé Jésù?
A fọ̀ ọ̀ mọ́ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn;
Ìwọ ha ń múra fún ilé dídan ni?
K' a wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?

A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀
Nínú ẹ̀jẹ̀ tí ń wẹ̀ ọkàn mọ́?
Aṣọ rẹ ha funfun? ó sì mọ́ láúláú
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?

Bọ́ ẹ̀wù ẹ̀érí-ẹ̀ṣẹ̀ sí àpákan,
K' a wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?
Ìsun kan ń san fún gbogbo ọkàn àìmọ́
Jọ̀ọ́ lọ wẹ̀ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn.

A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀
Nínú ẹ̀jẹ̀ tí ń wẹ̀ ọkàn mọ́?
Aṣọ rẹ ha funfun? ó sì mọ́ láúláú
A wẹ̀ ọ n' nú ẹ̀jẹ̀ Od'-àgùtàn?