Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 263: A Sìn Olùràpadà Wa

Buried Beneath The Yielding Wave

A sìn Olùràpadà wa.
Sínú 'bòjì omi;
A f' ìgbàgbọ́ rí I nín' omi
Àti b' Ó ṣe dìde.

Báyìí l' àwọn wọ̀nyí lónìí,
Fi ìtara wọn hàn,
Wọ́n mú gbogbo odòdó ṣe;
B' Olúwa wa ti ń fẹ́.

A f' ayọ̀ tẹ̀ lé iṣẹ́ Rẹ
A fẹ́ ṣe iṣẹ́ Rẹ;
K' a lè kú gẹ́gẹ́ bí Tire.
K' a sì lè bá A jọba.

Ojú Rẹ m' ọkàn wa sójí,
Ó lé èrù wa lọ;
Àṣẹ Rẹ f' agbára fún wa,
A sì f' ayọ̀ gbọ́ràn.