Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 262: N Ó Ṣe Tẹ̀ Lé Ẹni Tí Mo Ń Sìn?
How Shall I Follow Him?
N ó ṣe tẹ̀ lé ẹni tí mo ń sìn?
N ó ṣe tẹ̀ lé ẹn' tí mo fẹ́?
Tàbí kí n yẹ ẹsẹ̀ kúrò l' ọ̀nà
'Búkún tó lọ sí ọ̀run?
Olúwa bí mo tilẹ̀ jìyà,
Jọ̀wọ́ má jẹ́ kí n ṣe oókọ Rẹ,
Yí 'jú mi s' òkè sí Kalfari,
Kí n lè wò ìjìyà Rẹ.
Jẹ́ kí n rò nípa ìrúbọ Rẹ,
Ní fífi ayọ̀ ọ̀run sílẹ̀,
Ní gbígb' ààwẹ̀, ní sísọ ná, ní jíjìyà
T' ọ̀sán t' órù.
Ìwọ ṣe yìí O sì kú fún mi!
Ìwọ kò tẹ́ 'ra Rẹ l' ọ̀run
Bí ìgbádùn ayé ti pọ̀ tó n ó fẹ́ Ọ
Ju gbogbo wọn lọ.