Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 260: Jésù Mo Ti Ṣe 'Lérí
O Jesus I Have Promised
Jésù mo ti ṣe 'lérí
Láti sìn Ọ d' òpin;
Máa wà l' ọ̀dọ̀ mi títí,
Bàbá mi, Ọ̀rẹ́ mi;
Èmi k' yóò bẹ̀rù ogun,
B' Ìwọ bá ń tòsí,
Èmi kò ní ṣáko lọ
Bó O bá f' ọ̀nà hàn mi.
Jẹ́ kí n mọ̀ pé O wà n' tòsí,
Ayé fẹjú mọ́ mi;
Ayé fẹ́ gbà ọkàn mi,
Ó sì fẹ́ tàn mi jẹ;
Ọ̀tá yí mi káàkiri
L' òde àti nínú
Ṣùgbọ́n Jésù sún mọ́ mi,
D' àábò bo ọkàn mi.
Jésù, 'wọ ti ṣe 'lérí
F' àwọn t' ó tẹ̀ lé Ọ,
Pé 'bikibi tó O bá wà,
N' ìránṣẹ́ Rẹ yóò wà;
Jésù mo ti ṣe 'pínnu
Láti sìn Ọ d' òpin.
Jẹ́ k' èmi lè tẹ̀ lé Ọ
Bàbá mi, Ọ̀rẹ́ mi!