Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 26: Jí Ọkàn Mi, Bá Oòrùn Jí

Awake My Soul and With the Sun

Jí ọkàn mi, bá oòrùn jí
Múra sí iṣẹ́ oòjọ́ rẹ;
Má ṣe lọ́ra, f' ayọ̀ dìde,
K' ó san gbèsè ẹbọ oòrọ̀.

Jí, gbọ́n 'ra nù, 'wọ ọkàn mi,
Yan 'pọ̀ rẹ pẹ̀l' àwọn ángẹ́lì
Tí wọ́n ń kọrin, ní gbogb' òru,
Ìyìn s' Ọba ayérayé.

Olúwa, mo tún èjẹ̀ jẹ,
T' ẹ̀ṣẹ̀ mi ká b' ìrí oòrọ̀;
Sọ èrò àti ìfẹ́ mi,
Sì f' Ẹ̀mí Rẹ̀ kún ọkàn mi.

Èrò ọ̀rọ̀ àt' iṣẹ́ mi,
Ṣàkóso gbogbo wọn lónì
K' èmi lè fi gbogbo 'pá mi
Ṣiṣe rere fún ọ̀gọ́ Rẹ̀.