Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 259: Kí Jésù Ha Nìkan Jìyà

Must Jesus Bear The Cross Alone

Kí Jésù ha nìkan jìyà
K' aráyé lọ l' ọ̀fẹ́ẹ́?
Erù ń bẹ f' olúkúlùkù,
Erù ń bẹ fún mi náà

Èm' ó ru àgbélébùú mi
Títí yóò fi gbà mí;
'Gbà náà n ó lọ 'lé lọ d' adé,
Tòr' adé ń bẹ fún mi.

Ní ilé ìtà Kristál náà,
Lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù;
N' ó gb' adé wúrà mi lélé
Ògo f' orúkọ Rẹ.