Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 254: Lásán L' Àfẹ́ Ayé Ń Pè Mí
Earthly Pleasure Vainly Call Me
Lásán l' àfẹ́ ayé ń pè mí,
Mo fẹ́ dàbí Jésù;
Ohun ayé kò ní dé mi,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Dàbí Jésù l' orin mi,
Nínú 'lé àt' àwùjọ;
Kí n jọ Jésù l' ọjọ́ọjọ́,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
A! Ó ti ja gbogbo ìdè.
Mo fẹ́ dàbí Jésù;
K' ọkàn mi lè sìn ín b' ó ti tọ́,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Dàbí Jésù l' orin mi,
Nínú 'lé àt' àwùjọ;
Kí n jọ Jésù l' ọjọ́ọjọ́,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Láti ayé sínú ògo,
Mo fẹ́ dà bí Jésù;
Là ó máa sọ ìtàn ayọ̀ náà,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Dàbí Jésù l' orin mi,
Nínú 'lé àt' àwùjọ;
Kí n jọ Jésù l' ọjọ́ọjọ́,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Kí O lè padé mi l' ọ̀run,
Mo fẹ́ dàbí Jésù;
Ko O lè sọ fún mi pé, 'ó ṣeun.
Mo fẹ́ dàbí Jésù.
Dàbí Jésù l' orin mi,
Nínú 'lé àt' àwùjọ;
Kí n jọ Jésù l' ọjọ́ọjọ́,
Mo fẹ́ dàbí Jésù.