Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 253: Jésù Ṣ' ayé Mi N' Ìmọ́lẹ̀

God Make My Life a Little Light

Jésù ṣ' ayé mi n' ìmọ́lẹ̀,
Láti tàn 'nú ayé;
K' èmi lè jẹ́ 'mọ́lẹ̀ níbi
Gbogbo tí mo bá lọ.

Jésù, ṣ' ayé mi ní 'tànná,
Tí ń f' ayọ̀ f' ènìyàn
Tí ó máa ń tàn ní ipò rẹ̀,
B' ibẹ̀ tilẹ̀ kéré.

Jésù ṣe ayé mi l' orin,
Tí ó ń tù ní nínú;
Tí ń fún elòmíì l' agbára
Tí ń mu 'n' akọrin dùn.

Jésù ṣe ayé mi l' ọ̀pàá
Fún 'simi aláààrẹ̀;
Kí 'lera àt' agbára mi
Wá f' aládùúgbò mi.

Jésù ṣ' èmi l' orin mímọ́,
Ti 'tùnú àt' ìyìn;
Tí ìgbàgbọ́ ti kì í tutù
L' ọ̀nà ìyànu Rẹ.