Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 250: Ìgbàgbọ́ Àwọn Bàbá Wa
Faith Of Our Fathers
Ìgbàgbọ́ àwọn bàbá wa
Kò bẹ̀rù idà àti 'ná
Ọkàn wa sì kún fún ayọ̀
Gbà t' á gbọ́ 'róyìn, 'gbàgbọ́ wọn
Ìgbàgbọ́ mímọ́ bàbá wa!
A ó s' òótọ́ sí Ọ títí 'kú.
Nínú ẹ̀wọ̀n àti 'dààmú
Ọkàn àwọn bàbá wa ń yọ̀,
Báwo ni ibà ti dùn tó
B' àwọn 'mọ wọn bá le ṣe bẹ́ẹ̀
Ìgbàgbọ́ mímọ́ bàbá wa!
A ó s' òótọ́ sí Ọ títí 'kú.
A ó ní 'fẹ́ ọ̀rẹ́ àt' ọ̀tá,
Nínú ìjàkadì ayé,
A ó sì f' ìfẹ́ ńlá róyìn Rẹ
Nínú ọ̀rọ̀ àt' iṣẹ́ wa,
Ìgbàgbọ́ mímọ́ bàbá wa!
A ó s' òótọ́ sí Ọ títí 'kú.