Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 246: Bàbá Mo F' Ayé Mi Fún Ọ

Father I Yield To Thee

Bàbá mo f' ayé mi fún Ọ
Yóò jẹ́ Tire nìkan;
Mo fi àfẹ́ ayé sílẹ̀
Mo tọ́ Ọ wá Olúwa.
Mo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ayé
Ẹ̀gàn oun òṣì rẹ̀,
Mo sá tọ́ Ọ wá, níbi tí
Ìmọ́lẹ̀ ń tàn títí.

Bàbá mo fi 'fẹ́ mi fún Ọ,
Tútù ni 'fẹ́ náà jẹ́;
Ìwọ dà 'fẹ́ gbígbóná Rẹ
Bò ọkàn ààrẹ̀ mi.
Kúrò lọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ tí í yẹ̀,
Nínú ìjì tí ń jà,
Mo rí ìfẹ́ ìyànu ńlá,
Lábẹ́ 'yè apá Rẹ

Bàbá mo f' ara mi fún Ọ,
N ó j' oníteriba;
Mo fẹ́ sìmí ní àyà Rẹ
Kí n sì máa gb' ohùn Rẹ,
S' ọkàn mi kó dàbí Tire
Kí n rí bí O ti rí,
Kí èrò àti ọ̀rọ̀ mi
Le máa jẹ́ nípa Rẹ

Bàbá mo f' ara mi fún Ọ
Ìrìnkírí mi pín,
Àdùn ayé d' ẹkún ìpè,
Wọ́n kò ní tàn mí mọ́.
Gbogbo ìyèméjì mi pín,
Ìbùkún ń bẹ fún mi;
N' ínú ìfẹ́ Rẹ nìkan ṣoṣo
Ni n ó sìmí títí.