Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 245: Olúwa, Èmi Ṣàá Ti Gb' Ohùn Rẹ

I Am Thine O Lord

Olúwa, èmi ṣàá ti gb' ohùn Rẹ,
Ó ń sọ ìfẹ́ Rẹ sí mi:
Ṣùgbọ́n mo ń fẹ́ ǹdé l' apá Ìgbàgbọ́;
Kí n le túbọ̀ sún mọ́ Ọ.

Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' àgbélébù tó O kú,
Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' ẹ̀jẹ̀ Rẹ t' ó níyè.

Yà mí sí mímọ́ fún iṣẹ́ Tire
Nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ:
Jẹ́ kí n fi ọkàn ìgbàgbọ́ wòkè
K' ìfẹ́ mi tẹ̀ sí Tire.

Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' àgbélébù tó O kú,
Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' ẹ̀jẹ̀ Rẹ t' ó ní ìyè.

A' ayọ̀ mímọ́ ti wákàtí kan,
Tí mo lò níb' ìtẹ́ Rẹ,
Gbà mo ń gbàdúrà sí Ọ Ọlọ́run
Tí a sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́.

Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' àgbélébù tó O kú,
Fà mí mọ́ra, mọ́ra, Olúwa,
Síb' ẹ̀jẹ̀ Rẹ t' ó ní ìyè.