Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 244: Nígbà Tí Ọkàn Mi Ṣì Rọ

Saviour While My Heart Is Tender

Nígbà tí ọkàn mi ṣì rọ,
Olúwa n' ó fi fún Ọ;
Mo fi gbogbo 'pá mi fún Ọ
Láti jẹ́ Tire nìkan.

Jésù gbà mí nísisìyí,
Jẹ́ k' ọkàn mi jẹ́ Tire;
Ṣe mi ní 'ránṣẹ́ olóòótọ́,
Fi 'fẹ́ ọ̀run k' ọkàn mi.

Olúwa ran mi níb' O fẹ́
Ṣàá tọ́ ìpá ọ̀nà mi;
K' oore-ọ̀fẹ́ Rẹ wà pẹ̀lú mi
T' ayọ̀ t' ayọ̀ ni n ó lọ.