Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 243: Ǹbá Le Jẹ́ Tire, Jésù Ọ̀wọ́n

I Would Be Dear Saviour, Wholly Thine

Ǹbá le jẹ́ Tire, Jésù ọ̀wọ́n,
Kọ́ mi bẹ́ẹ̀, kọ́ mi bẹ́ẹ̀.
N ó máa ṣe ìfẹ́ Rẹ Olúwa,
Jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́

Jẹ́ Tire... jẹ́ Tire,
Kí n jẹ́ Tire l' ẹ̀jẹ̀ mi;
Jẹ́ Tire... jẹ́ Tire
Tire nìkan, Olúwa.

Kíl' àdùn àt' ọlá ayé jẹ́?
Láìsí Rẹ láìsí Rẹ;
N ó kọ wọ́n sílẹ̀ f' orúkọ Rẹ
Èyí l' ọ̀rọ̀ mi.

Jẹ́ Tire jẹ́ Tire,
Kí n jẹ́ Tire l' ẹ̀jẹ̀ mi;
Jẹ́ Tire... jẹ́ Tire
Tire nìkan, Olúwa.

Mo kọ àìpé ayé sílẹ̀,
Sún mọ́ mi sún mọ́ mi
L' ọ̀dọ̀ Rẹ mo rí ohun gbogbo,
'Tùnú mi l' èyí.

Jẹ́ Tire jẹ́ Tire,
Kí n jẹ́ Tire l' ẹ̀jẹ̀ mi;
Jẹ́ Tire... jẹ́ Tire
Tire nìkan, Olúwa.