Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 242: Jésù Mo Gb' Àgbélébù Mi

Jesus I, My Cross, Have Taken

Jésù mo gb' àgbélébù mi,
Kí n le máa tọ́ Ọ lẹ́yìn;
Mo kọ àfẹ́ ayé sílẹ̀;
'Wọ l' ohun gbogbo fún mi:
Bí iní gbogbo ṣègbé,
Tí èrò mi gbogbo pín;
Síbẹ̀ olóró ni mo jẹ́!
'Gbà t' Olúwa jẹ́ t' èmi.

Ayé le kẹ́gàn kò kọ̀ mi.
Wọ́n ti k' Olùgbàlà rí;
Ọkàn ènìyàn kún f' ẹ̀tàn
'Wọ nìkan ni olóòótọ́.
Ìbànújẹ́ kò le ṣe nkan
B' ìfẹ́ Rẹ bá wà fún mi;
Ayọ̀ kò sì le dùn mọ́ mi
B' ìfẹ́ Rẹ kò sí n' ínú mi.

Ọkàn mi gbà ìgbàlà Rẹ,
Borí ẹ̀ṣẹ̀ àt' ẹ̀rù.
F' ayọ̀ wà ní ipòkipò,
Máa ṣiṣẹ́, sì máa jìyà;
Rò t' Ẹ̀mí t' ó wà nínú rẹ;
Àt' ìfẹ́ Bàbá sí ọ,
W' Olùgbàlà t' ó kú fún ọ;
Ọmọ ọ̀run má ṣe kún!

Ǹjẹ́ kọjá lát' oore s' ògó,
N' n' àdúrà oun ìgbàgbọ́
Ọjọ́ àìlópin wà fún ọ,
Bàbá yóò mú ọ dé 'bẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ l' ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ pín.
Ọjọ́ àjò rẹ ń búṣe,
Ìrètí yóò padà s' ayọ̀,
Àdúrà s' orin ìyìn.