Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 241: Gbà t' Ọ̀pọ̀ F' Olúwa Sílẹ̀

When Many From The Saviour Turned

Gbà t' ọ̀pọ̀ f' Olúwa sílẹ̀,
Tí wọ́n kò bá A rìn mọ́,
Àwọn díẹ̀ l' ó kù t' ó ní
Ìfẹ́ wọn ìṣáájú;
Àwọn wọ̀nyí l' Ó wí fún pé:
Ẹ̀yin hà fẹ́ lọ pẹ̀lú bí?

Síbẹ̀ a gbọ́ ìdáhùn wọn,
Ọ̀dọ̀ tal' á ó lọ?
Ìwọ l' ọ̀rọ̀ 'yè àìlópin,
A mọ̀, a gbàgbọ́ pé
Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run,
A bẹ̀ Ọ, máa jẹ́ k' á lọ láé.

Síbẹ̀ kòlòkòlò ní 'hò
Àwọn ẹyẹ n' ìtẹ́,
Ẹni tí ẹ̀yin ń tẹ̀lé kò
Níbi t' yóò f' orí lé;
Ẹ ó hà n' ìpín-in pẹ̀lú Rẹ?
Yóò rọ̀rùn fún yín láti lọ.

Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọ pọ̀
'Fẹ́ elòmíràn tútù.
Bẹ́ẹ̀ l' ọ̀pọ̀ f' ọ̀nà 'yè sílẹ̀,
Wọ́n ń rìn kúrò n' ín' agbo;
Bí gbogb' ènìyàn kọ O sílẹ̀,
Olúwa, àwa kì yóò lọ.