Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 239: Fà Mí Olùgbàlà Mi Ọ̀wọ́n

Nearer Still Nearer

Fà mí Olùgbàlà mi ọ̀wọ́n,
Gírigíri mọ́ra sí ọkàn Rẹ:
F' ọwọ́ gbà mí mú mọ́ àyà Rẹ,
Rádò bò mí l' ẹ̀bùté sìmí náà.
Rádò bò mí l' ẹ̀bùté sìmí náà.

N kò r' ohun kan mú wá s' ọ̀dọ̀ Rẹ.
N kò l' ẹ̀bùn tí mo le fún Ọba mi;
À fi ìrọ̀bínújẹ́ ọkàn;
Fún mi ní Ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀jẹ̀ Rẹ
Fún mi ní Ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀jẹ̀ Rẹ.

Mo di Tire gbangba Olúwa,
Mo kọ 'wà ẹ̀ṣẹ̀ oun wèrè sílẹ̀;
Gbogbo afẹ́ àt' ògo-asán,
Fún mi ní Jésù t' ó kú l' or' igi,
Fún mi ní Jésù t' ó kú l' or' igi.

Nígbà tí ẹ̀mí ayé bá pín,
N ó sìmí láìléwu nínú ògó;
Títí ayérayé l' èm' ó wà.
L' ọ̀dọ̀ Rẹ, Olùgbàlà l' ọ̀dọ̀ Rẹ
L' ọ̀dọ̀ Rẹ, Olùgbàlà l' ọ̀dọ̀ Rẹ.