Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 238: Bí Mo Ti Rí-Láìsí Wàwí
Just As I Am Without One Plea
Bí mo ti rí-láìsí wàwí
Ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀jẹ̀ Rẹ:
Bó O sì ti pè mí pé kí n wá.
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.
Bí mo ti rí láìdúró pẹ́,
Mo fẹ́ k' ọkàn mi mọ́ tòótọ́,
S' ọ̀dọ̀ Rẹ tó O le wẹ̀ mi mọ́,
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.
Bí mo ti rí—b' ó tilẹ̀ jẹ́
Ìjà l' òde, ìjà nínú;
Ẹ̀rù l' òde, ẹ̀rù nínú
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.
Bí mo ti rí---òṣì, àárẹ̀,
Mo sì ń wá ìmúlàrádá;
Ìwọ l' O le ṣ' àwòtán mi,
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.
Bí mo ti rí--- 'Wọ ó gbà mí,
'Wọ ó gbà mí t' ọwọ́ t' ẹsẹ̀;
'Torí mo gbà 'lérí Rẹ gbọ́,---
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.
Bí mo ti rí--- ìfẹ́ Tire
L' ó ṣẹ̀tẹ̀ mi pátápátá:
Mo di Tire, Tire nìkan,
Olùgbàlà, mo dé,
mo dé.