Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 237: Ọkàn Mi, A Tún Fi Jésù Lọ́ Ọ
Once More, My Soul, Thy Saviour Through The Word
Ọkàn mi, a tún fi Jésù lọ́ ọ
Lẹ́ẹ̀kan sí i n' 'nú ọ̀rọ̀ Rẹ;
Nísisìyí, Olúwa n ó pínnu,
N kí o hà gbà Tire?
Mo fẹ́, mo fẹ́,
B' Ọlọ́run ṣe ránwọ́
Èmi fẹ́ jẹ́ Tire,
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yebíye l' O fi rà mí,
Èmi yóò jẹ́ Tire.
Níp' oore-ọ̀fẹ́ l' èm' ó rí àánú gbà,
Ìfẹ́ Rẹ ṣẹ́gun mi:
Krístì, Ìwọ ni èmi ó gbà gbọ́,
N ó sì gbékèlé Ọ!
Mo fẹ́, mo fẹ́,
B' Ọlọ́run ṣe ránwọ́
Èmi fẹ́ jẹ́ Tire,
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yebíye l' O fi rà mí,
Èmi yóò jẹ́ Tire.
Olúwa Ìwọ mọ̀ àìlera mi
Bí n kò fẹ́ ṣako,
'Wọ nìkan l' ó le fún mi
l' agbára Láti jọ́sìn fún Ọ.
Mo fẹ́, mo fẹ́,
B' Ọlọ́run ṣe ránwọ́
Èmi fẹ́ jẹ́ Tire,
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yebíye l' O fi rà mí,
Èmi yóò jẹ́ Tire.
Olúwa f' oore-ọ̀fẹ́ fún wa lónìí,
K' á le jùmọ̀ korin;
Kí gbogbo wa sọ tọkàntọkàn pé
Èmi yóò jẹ́ ti Krístì.
Mo fẹ́, mo fẹ́,
B' Ọlọ́run ṣe ránwọ́
Èmi fẹ́ jẹ́ Tire,
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yebíye l' O fi rà mí,
Èmi yóò jẹ́ Tire.
Àwọn t' ó tọ́ Ọ wá n' ìgbà-ayé Rẹ,
Láti tọrọ 'bùkún.
Mo fẹ́ ní ìdáhùn tí wọ́n rí gbà
Oun náà l' á gb' ọkàn lé.
Mo fẹ́, mo fẹ́,
B' Ọlọ́run ṣe ránwọ́
Èmi fẹ́ jẹ́ Tire,
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ 'yebíye l' O fi rà mí,
Èmi yóò jẹ́ Tire.