Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 236: Jésù Wí, Ìránṣẹ́ Rẹ Ń Gbọ́
Master Speak! Thy Servant Heareth
Jésù wí, ìránṣẹ́ Rẹ ń gbọ́
Ó ń dúró dé ọ̀rọ̀ Rẹ;
Ó ń fẹ́ gb' ohùn máràyà Rẹ,
Olúwa jọ̀ọ́ jẹ́ k' á gbọ́;
Mo tẹ etí mi Olúwa,
Kín ni 'wọ ní wí fún mi?
Pè mí l' orúkọ Olúwa,
Kí n le mọ̀ pé èmi ni,
Wí k' èmi le tètè tẹ̀ lé e
Pẹ̀lú 'ṣiṣẹ́ t' ó dájú;
Síbi t' ìwọ ń dà 'gbọ́ Rẹ
Nín' Ojìjì àpáta.
Mo kéré jù, síbẹ̀ sọ̀rọ̀,
Máṣe jẹ́ kí n lọ láì gbọ́;
Wí Olúwa 'tór' ìwọ mọ̀
Ìfẹ́ gbígbón' ọkàn mi;
Gbogbo àìní ọkàn mi,
Wí k' èmi le r' ìbùkún.
Wí Olúwa mú mi múra,
'Gbà tí mo bá gb' ohùn Rẹ;
Pẹ̀lú ìgbọ́ràn t' ó dájú
Láti tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Rẹ;
Mo tẹ etí mi Olúwa,
Wí Olúwa wí fún mi.