Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 235: Tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Ọlọ́run
Temple Of God's Holy Spirit
Tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Ọlọ́run
Ni ara yìí tèmi kọ́;
Tí a fi ẹ̀jẹ̀ Jésù rà
Fún ògó orúkọ Rẹ
Tèmi kọ́ tèmi kọ́,
Fún ògó orúkọ Rẹ ni.
Tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Ọlọ́run
Tá a kọ́ fún Ọlọ́run mi,
Ṣe 'búgbé Rẹ láìlábààwọ́n
K' ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ má bá a jẹ́
Tèmi kọ́ tèmi kọ́,
Ṣe 'búgbé Rẹ ní mímọ́.
Jésù fún mi ní Ẹ̀mí Rẹ
Mo ń tọrọ 'wà mímọ́ Rẹ;
Jẹ́ k' èmi gbé ẹwà Rẹ wọ̀,
F' ìwà mímọ́ Rẹ wọ̀ mi
Tèmi kọ́ tèmi kọ́,
F' ìwà mímọ́ Rẹ wọ̀ mi.