Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 233: Tire Láéláé! Ọlọ́run

Thine Forever God Of Love

Tire láéláé! Ọlọ́run,
F' ìfẹ́ gbọ́ àdúrà wa:
Jẹ́ k' á jẹ́ Tire títí,
L' ayé yìí àti láéláé.

Tire láéláé! Olúwa
D' àábo bò wá l' ayé wa.
Wọ n' ìyè, Ọ̀nà òótọ́
Tó wá sí ilú ọ̀run.

Tire láéláé! Àbùkún
L' àwọn O fún n' ìsìmí!
Olùgbàlà, Ọ̀rẹ́ wa,
Gbà 'jà wa jà dé ópín.

Tire láéláé! Jésù, pa
Àwọn àgùntàn Rẹ mọ́;
Lábẹ́ ìṣọ́ Rẹ nìkan,
F' oore Rẹ tó gbogbo wa.

Tire láéláé! Àmọ̀nà
Tí ń pèsè fún àìní wa,
Tí ń fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jí wa,
Olúwa tó wá d' ọ̀run.