Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 23: Bàbá Mi Fún Oòrùn Jẹ̀jẹ̀
My Father for Another Night
Bàbá mi fún oòrùn jẹ̀jẹ̀
Ní òru t' ó kọjá,
Fún ayọ̀ ìmọ́lẹ̀ oòrọ̀
'Búkún ní f' oókọ Rẹ̀.
Lẹ́ẹ̀kan sí l' ọjọ́ títun yìí,
Mo f' ara mi fún ọ;
Jẹ́ kí èmi ṣe, kí n sì jẹ́,
Ohun tí Ìwọ ń fẹ́.
Ohunkóhun tí mo bá ṣe,
Tí mo sọ tàbí rò,
Jẹ́ kí n' wá ọ̀gọ́ Rẹ̀, kí n sì
Ṣe wọ́n l' oókọ Jésù.
Bàbá mi, nítorí Jésù
Gbà mí, sì búkún mi,
Kí O sì ṣìn mí ní oní
Sí ọ̀nà òdodo.