Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 229: Mo Ń Bọ̀ Níb' Àgbélébùú
I Am Coming To The Cross
Mo ń bọ̀ níb' àgbélébùú;
Èmi òtòṣì jùlọ;
Mo ka gbogbo nkan s' òfo
Láti rí 'ìgbàlà kíkún.
Mo gbékèlé O, Jésù,
Ọd' àgùntàn Kalfarì;
Mo fi 'rẹ̀lẹ̀ tẹríba
Gbà mí, Jésù, lónìí yìí.
Ọkàn mi ti ń wá Ọ pẹ́
Ẹ̀ṣẹ̀ ti ń bá mi gbé pẹ́,
Jésù ń fi 'fẹ́ sọ fún mi,
"N ó wẹ gbogb' ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù."
Mo gbékèlé O, Jésù,
Ọd' àgùntàn Kalfarì;
Mo fi 'rẹ̀lẹ̀ tẹríba
Gbà mí, Jésù, lónìí yìí.
Mo fi gbogbo rẹ̀ fún Ọ,
Ọ̀rẹ́ àt' iṣúrà mi
K' ọkàn àt' ara mi
Jẹ́ Tire títí láéláé.
Mo gbékèlé O, Jésù,
Ọd' àgùntàn Kalfarì;
Mo fi 'rẹ̀lẹ̀ tẹríba
Gbà mí, Jésù, lónìí yìí.
Jésù fi ayọ̀ kún mi,
Ó sì sọ mi di pípe,
Mo ní ìlera pípe,
Ògó ni f' Ọd' àgùntàn.
Mo gbékèlé O, Jésù,
Ọd' àgùntàn Kalfarì;
Mo fi 'rẹ̀lẹ̀ tẹríba
Gbà mí, Jésù, lónìí yìí.