Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 228: Jésù Mímọ́ Onírẹ̀lè

Blessed Jesus, Meek And Lowly

Jésù mímọ́ Onírẹ̀lè
Ṣe 'búgbé Rẹ pẹ̀lú wa;
Àwa fẹ́ jẹ́ mímọ́ bí Rẹ,
A sì fẹ́ b' Ọlọ́run rìn.
A fẹ́ ẹ̀mí 'rẹ̀lẹ̀ bí Rẹ
A fẹ́ kó O wá gb' ọkàn wa;
K' á má bàá ṣègbé láìsí Rẹ.
A bẹ̀ Ọ wá bá wa gbé.

Jọ̀ọ́ tọ́ wa ní ọ̀nà ọ̀run,
B' ọ̀nà náà tilẹ̀ ṣòro;
Jẹ́ kí ìdánwò tí a ń rí
Mú wa sún mọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ,
A rí n' ínú ìgbé-ayé Rẹ
B' ayé ṣe fi Ọ ṣẹ̀sìn;
Ìjìyà l' ó ń ṣáájú ògó
Ìyà l' ó ń ṣáájú adé.

Jẹ́ k' á ṣiṣẹ́ nín' ọgbà Rẹ,
Jẹ́ k' á sọ ti oore Rẹ;
Pẹ̀lú Rẹ gbogb' ohun dára,
Àsán ni wọ́n láìsí Rẹ.
'Gbà tí ojìjì alẹ́ ń bọ̀,
L' ayé òkùnkùn wa yìí,
Olùgbàlà wa, bá wa gbé,
Títí ilé yóò fi mọ́.

'Gbà náà jẹ́ k' á bá O jọba
Pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́
Níbi t' ẹ̀ṣẹ̀ kò le yà wá
Kúrò ní ọ̀dọ̀ Rẹ láé.
Níbẹ̀ l' á ó b' àwọn áńgẹ́lì
Yìn Ọba Oníb' oore,
Ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́
Ikú láé àti láéláé.