Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 227: Mo K' Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Lé Jésù

I Lay My Sin On Jesus

Mo k' ẹ̀ṣẹ̀ mi lé Jésù
Ọd' àgùntàn mímọ́;
Ó rù gbogbo èrù mi,
Ó sọ mi d' óminira.
Ó sọ mi d' óminira.

Mo rù ẹbí mi tọ́ Ọ wá
Kó O wẹ ẹ̀rí mi nù
K' ẹ̀jẹ̀ Rẹ, ìyebíye,
Le sọ mi di mímọ́
Le sọ mi di mímọ́.

Mo k' àìní mi lé Jésù,
Tire l' ohun gbogbo;
Ó wò àrùn mi gbogbo sàn,
Ó r' ẹ̀mí mi padà,
Ó r' ẹ̀mí mi padà.

Mo fẹ́ kí n rí bí Jésù,
T' ọkàn Rẹ kún fún 'fẹ́:
Mo fẹ́ kí n rí bí Jésù,
Ọmọ Mímọ́ Bàbá
Ọmọ Mímọ́ Bàbá.

Mo fẹ́ kí n bá Jésù gbé
Láàárín ẹgbẹ́ mímọ́
Kí n bá wọn korin ìyìn,
Orin t' áńgẹ́lì ń kọ
Orin t' áńgẹ́lì ń kọ.