Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 223: Lù Agogo Ọ̀run Ayọ̀

Ring The Bells Of Heaven

Lù agogo ọ̀run ayọ̀ ń bẹ lónìí,
Fún ọkàn t' ó ronúpìwàdà
Wò Bàbá b' ó ti ń lọ padé rẹ̀ l' ọ̀nà,
Ó ń kí aṣako ọmọ kàábọ̀.

Ògó! Ògó! gbọ́ b' áńgẹ́l' tí ń kọ,
Ògó! Ògó! gb' ohùn ayọ̀ hárpù
Àwọn tá a rà padà dàb' ìgbì òkun,
Wọ́n ń korin ayọ̀ ìràpadà.

Lù agogo ọ̀run ayọ̀ ń bẹ lónìí
A m' ẹlẹ́ṣẹ̀ b' Ọlọ́run lájà;
A yọ ọkàn kan k' rọ 'nú òfin ẹ̀ṣẹ̀
A tún-un bí, a sọ ọ́ d' ọmọ ìgbàlà.

Ògó! Ògó! gbọ́ b' áńgẹ́l' tí ń kọ,
Ògó! Ògó! gb' ohùn ayọ̀ hárpù
Àwọn tá a rà padà dàb' ìgbì òkun,
Wọ́n ń korin ayọ̀ ìràpadà.

Lù agogo ọ̀run ayọ̀ ń bẹ lónìí
Áńgẹ́lì ń kéde orin ayọ̀
Rọ ìhìn ayọ̀ náà ká ibí gbogbo
Pé ọkàn kan d' ọmọ ìgbàlà.

Ògó! Ògó! gbọ́ b' áńgẹ́l' tí ń kọ,
Ògó! Ògó! gb' ohùn ayọ̀ hárpù
Àwọn tá a rà padà dàb' ìgbì òkun,
Wọ́n ń korin ayọ̀ ìràpadà.