Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 222: Mo Ti Ṣako Jìnà Sílé
I've Wandered Far Away from God
Mo ti ṣako jìnà sílé,
Mo fẹ́ wá sí 'lé;
Mo ti ń tọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́yìn ti pẹ́,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń bọ̀ wá sí 'lé
N kò ní ṣako mọ́
Nà 'wọ̀ ìfẹ́ Rẹ sí mi;
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ti f' àkókò púpọ̀ sòfo,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Pẹ̀l' omijé ni mo ń kẹ̀dùn,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń bọ̀ wá sí 'lé
N kò ní ṣako mọ́
Nà 'wọ̀ ìfẹ́ Rẹ sí mi;
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Ẹ̀ṣẹ̀ àt' ìṣànsà sù mí
Mo fẹ́ wá sí 'lé;
N ó d' ìfẹ́ àt' Ọ̀rọ̀ Rẹ mú,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń bọ̀ wá sí 'lé
N kò ní ṣako mọ́
Nà 'wọ̀ ìfẹ́ Rẹ sí mi;
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Ìrètí àt' ẹ̀bẹ̀ mi ni
Mo fẹ́ wá sí 'lé;
Pé Jésù kú, Ó kú fún mi,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń bọ̀ wá sí 'lé
N kò ní ṣako mọ́
Nà 'wọ̀ ìfẹ́ Rẹ sí mi;
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń fẹ́ ẹ̀jẹ̀ 'wẹ̀nùmọ́ Rẹ
Mo fẹ́ wá sí 'lé;
Fọ̀ mi mọ́ kí n mọ́ láú bí snò,
Mo fẹ́ wá sí 'lé.
Mo ń bọ̀ wá sí 'lé
N kò ní ṣako mọ́
Nà 'wọ̀ ìfẹ́ Rẹ sí mi;
Mo fẹ́ wá sí 'lé.