Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 220: B' Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Ti Pọ̀ Tó Yìí

Chief of Sinners Though I be

B' ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó yìí
Síbẹ̀, Jésù kú fún mi;
Ó kú kí n le wà l' ọ̀run,
Ó kú kí n má bàá le kú;
B' ẹka ti rí s' àjàrà,
Tire l' èmi, Òun t' èmi.

'Fẹ́ ti Jésù ní sí wà,
Ga jù òkè ọ̀run lọ,
Ó jìn jù gbogbo òkun,
Ó wà títí ayérayé;
Ìfẹ́ tí ó wá mi rí
Nígbà tí èmi kò wá A.

B' ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó yìí,
Kríst' l' ohun gbogbo fún mi,
Ó mọ̀ gbogbo àìní mi,
Gbogb' ẹ̀dùn mi ni Tire;
Kò s' ewu ní ọ̀dọ̀ Rẹ,
Ó ń ṣe 'tọ́jú ọkàn mi.